Lúùkù 8:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Ǹjẹ́ òwe náà ni èyí: irúgbìn ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

12. Àwọn ti ẹ̀bá ọ̀nà ni àwọn tí ó gbọ́ nígbà náà ni Èṣù wá ó sì mú ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn wọn, kí wọn má ba à gbàgbọ́, kí a sì gbà wọ́n là.

13. Àwọn ti orí àpáta ni àwọn, tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ náà, àwọn wọ̀nyí kò sì ní gbòǹgbò, wọ́n á gbàgbọ́ fún sáà díẹ̀; nígbà ìdánwò, wọn á padà sẹ́yìn.

Lúùkù 8