Lúùkù 6:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú sínágọ́gù lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún rọ.

7. Àti àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí ń ṣọ́ ọ, bí yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án.

8. Ṣùgbọ́n ó mọ ìrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrin.” Ó sì dìde dúró.

Lúùkù 6