Lúùkù 6:35-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀ta yín kí ẹ̀yin sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ ọ̀gá ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣeun fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.

36. Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin ní àánú, gẹ́gẹ́ bí Baba yín sì ti ní àánú.

37. “Ẹ má ṣe dáni lẹ́jọ́, a kì yóò sì dá yín lẹ́jọ́: ẹ má ṣe dáni lẹ́bi, a kì yóò sì dá yín lẹ́bi: ẹ dáríjì, a ó sì dáríjì yín.

38. Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín; òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín: nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.”

39. Ó sì pa òwe kan fún wọn: “Afọ́jú ha lè ṣe amọ̀nà afọ́jú bí? Àwọn méjèèjì kọ́ ni yóò ṣubú sínú ihò bí?

40. Ẹni tí a ń kọ́ kì í ju olùkọ́ rẹ̀ lọ: ṣùgbọ́n olúkúlùkù ẹni tí ó ba pé, yóò dàbí olùkọ́ rẹ̀.

41. “Èéṣe tí ìwọ sì ń wo èérún igi tí ń bẹ lójú arákùnrin rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyèsí ìtì igi tí ń bẹ lójú ara rẹ?

Lúùkù 6