Lúùkù 5:33-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Wọ́n wí fún un wí pé “àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù a máa gbàwẹ̀, wọn a sì máa gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn àwọn Farisí ṣùgbọ̀n àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ a máa jẹ, wọn a sì máa mu pẹ̀lú.”

34. Jésù sì dáhùn ó wí fún wọn pé, “Ǹjẹ́ ó seé se kí àwọn àlejò ọkọ ìyàwó máa gbàwẹ̀ nígbà tí ọkọ ìyàwó wà pẹ́lú wọn bí?

35. Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀ nígbà tí a ó gba ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyìí ni wọn yóò gbàwẹ̀.”

Lúùkù 5