Lúùkù 5:16-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ṣùgbọ́n ésù a máa yẹra kúrò, òun á sì máa dáwà láti gbàdúrà.

17. Ní ijọ́ kan, bí ó sì ti ń kọ́ni, àwọn Farisí àti àwọn amòfin jókòó pẹ̀lú rẹ̀, àwọn tí ó ti àwọn ìletò Gálílì gbogbo, àti Jùdíà, àti Jerúsálémù wá: agbára Olúwa sì ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú wọn láradá.

18. Sáà sì kíyèsí i, àwọn Ọkùnrin kan gbé ẹnikantí ó ní àrùn egba wà lórí àketè: wọ́n ń wá ọ̀nà àti gbé e wọlé, àti láti tẹ́ ẹ ṣíwájú Jésù.

19. Nígbà tí wọn kò sì rí ọ̀nà tí wọn ìbá fi gbé e wọlé nítorí ìjọ ènìyàn, wọ́n gbé e gun òkè àjà ilé lọ, wọ́n sọ̀ ọ́ kalẹ̀ sí àárín èrò ti òun ti àketè rẹ̀ níwájú Jésù.

20. Nígbà tí ó sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó wí pé, “Ọkùnrin yìí, a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.” (Luk 7.48,49.)

21. Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí bẹ̀rẹ̀ sí í gbérò wí pé, “Ta ni eléyìí tí ń sọ ọ̀rọ̀ òdì? Ta ni ó lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini bí kò ṣe Ọlọ́run nìkan ṣoṣo.” (Isa 43.25.)

22. Jésù sì mọ ìrò inú wọn, ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?

23. Èwo ni ó yá jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́,’ tàbí láti wí pé, ‘Dìde kí ìwọ sì má a rìn’?

24. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ọmọ ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini…” Ó wí fún ẹlẹ́gbà náà pé, “Mo wí fún ọ, dìde, sì gbé àketè rẹ, kí o sì máa lọ sí ilé!”

25. Ó sì dìde lọ́gán níwájú wọn, ó gbé ohun tí ó dùbúlẹ̀ lé, ó sì lọ sí ilé rẹ̀, ó yin Ọlọ́run lógo.

26. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo, ẹ̀rù sì bà wọ́n, wọ́n ń wí pé, “Àwá rí ohun abàmì lónì-ín.”

27. Lẹ́hìn èyí, Jésù jáde lọ, ó sì rí agbowó òde kan tí à ń pè ní Léfì ó jòkòó sí ibi tí ó ti ń gba owó òde, Jésù sì wí fún un pé “Tẹ̀lé mi,”

28. Léfì sì fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì ń tẹ̀lé e.

29. Léfì sì ṣe àṣè ńlá kan fún Jésù ní ilé rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn mìíràn sì ń jẹun pẹ̀lú wọn.

30. Ṣùgbọ́n àwọn Farisí, àwọn olùkọ́ òfin tí ó jẹ́ ara wọn fi wọ́n hàn sí àwọn ọmọ ẹ̀hìn “èéṣe tí ẹ̀yin fi ń jẹun tí ẹ sì ń mú pẹ́lú àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”

31. Jésù dáhùn ó wí fún wọn pé “Ẹni tí ara rẹ̀ le kò nílò oníṣègùm, bí kò ṣe ẹni tí ara rẹ̀ kò dá.”

32. Èmí kò wá láti pe àwọn olódodo bí kò ṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ sí ìrònúpìwàdà.

Lúùkù 5