9. Èsu sì mú un lọ sí Jerúsálémù, ó sì gbé e lé ṣóńṣo tẹ́ḿpílì, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí:
10. A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ,láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ: (fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pa ọ́ mọ́)
11. Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè,kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
12. Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”