Lúùkù 24:50-53 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

50. Ó sì mú wọn jáde lọ títí wọ́n fẹ́rẹ̀ dé Bétanì, nígbà tí ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.

51. Ó sì ṣe, bí ó ti ń súre fún wọn, ó yà kúrò lọ́dọ̀ wọn, a sì gbé e lọ sí ọ̀run.

52. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì padà lọ sí Jerúsálémù pẹ̀lú ayọ̀ púpọ̀:

53. Wọ́n sì wà ní tẹ́ḿpìlì nígbà gbogbo, wọ́n ń fi ìyìn, àti ìbùkún fún Ọlọ́run. Àmín.

Lúùkù 24