Lúùkù 24:45-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.

46. Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kírísítì jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ijọ́ kẹ́ta kúrò nínú òkú:

47. Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálémù lọ.

48. Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.

Lúùkù 24