Lúùkù 24:31-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ojú wọn sì là, wọ́n sì mọ̀ ọ́n; ó sì nù mọ́ wọn ní ojú

32. Wọ́n sì bá ara wọn sọ pé, “Ọkàn wa kò ha gbiná nínú wa, nígbà tí ó ń bá wa sọ̀rọ̀ tí ó sì ń túmọ̀ ìwé mímọ́ fún wa!”

33. Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerúsálémù, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn,

34. Èmí wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Símónì!”

35. Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mímọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.

36. Bí wọ́n sì ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí Jésù tìkararẹ̀ dúró láàrin wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Àlààáfíà fún yín.”

37. Ṣùgbọ́n àyà fò wọ́n, wọ́n sì díjì, wọ́n ṣe bí àwọn rí ẹ̀mí kan.

38. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?

39. Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

40. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.

41. Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”

42. Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.

43. Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.

44. Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mósè, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Sáàmù, nípasẹ̀ mi.”

45. Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.

46. Ó sì wí fún wọn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni a ti kọ̀wé rẹ̀, pé: Kí Kírísítì jìyà, àti kí ó sì jíǹde ní ijọ́ kẹ́ta kúrò nínú òkú:

47. Àti pé kí a wàásù ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lórúkọ rẹ̀, ní orílẹ̀ èdè gbogbo, bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálémù lọ.

48. Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí.

49. Sì kíyèsí i, mo rán ìlérí Baba mi sí yín: ṣùgbọ́n ẹ jókòó ní ìlú Jerúsálémù, títí a ó fifi agbára wọ̀ yín, láti òkè ọ̀run wá.”

Lúùkù 24