Lúùkù 23:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. (Ṣùgbọ́n kò lè ṣàì dá ọ̀kan sílẹ̀ fún wọn nígba àjọ ìrékọjá.)

18. Wọ́n sì kígbe sókè nígbà kan náà, pé, “Mú ọkùnrin yìí kúrò, kí o sì dá Bárábà sílẹ̀ fún wa!”

19. Ẹni tí a sọ sínú túbú nítorí ọ̀tẹ̀ kan tí a ṣe ní ìlú, àti nítorí ìpànìyàn.

20. Pílátù sì tún bá wọn sọ̀rọ̀, nítorí ó fẹ́ dá Jésù sílẹ̀.

21. Ṣùgbọ́n wọ́n kígbe, wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélèbú, kàn án mọ àgbélèbú!”

22. Ó sì wí fún wọn lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé, “Èéṣe, búburú kínni ọkùnrin yìí ṣe? Èmi kò rí ọ̀ràn ikú lára rẹ̀: nítorí náà èmi ó nà án, èmi ó sì fi í sílẹ̀.”

23. Wọ́n túbọ̀ tẹramọ́ igbe ńlá, wọ́n ń fẹ́ kí a kàn án mọ́ àgbélèbú, Ohùn tiwọn àti ti àwọn olórí àlùfáà borí tirẹ̀.

24. Pílátù sí fi àṣẹ sí i pé, kí ó rí bí wọ́n ti ń fẹ́.

25. Ó sì dá ẹni tí wọ́n fẹ́ sílẹ̀ fún wọn, ẹni tí a tìtorí ọ̀tẹ̀ àti ìpànìyàn sọ sínú túbú; ṣùgbọ́n ó fi Jésù lé wọn lọ́wọ́.

26. Bí wọ́n sì ti ń fà á lọ, wọ́n mú ọkùnrin kan, Símónì ara Kírénè, tí ó ń ti ìgbéríko bọ̀, òun ni wọ́n sì gbé àgbélèbú náà lé, kí ó máa rù ú lọ tẹ̀lé Jésù.

27. Ìjọ ènìyàn púpọ̀ ni ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, àti àwọn obìnrin, tí ń pohùnréré ẹkún

28. Ṣùgbọ̀n Jésù yíjú padà sí wọn, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Jerúsálémù, ẹ má sọkún fún mi, ṣùgbọ́n ẹ sọkún fún ara yín, àti fún àwọn ọmọ yín.

Lúùkù 23