Lúùkù 21:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. “Ohun tí ẹ̀yin ń wò wọ̀nyí, ọjọ́ ń bọ̀, nígbà tí a kì yóò fi òkúta kan sílẹ̀ lórí èkejì tí a kì yóò wó lulẹ̀.”

7. Wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀, pé, “Olùkọ́, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò rí bẹ́ẹ̀? Àti àmì kíní yóò wà, nígbà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ?”

8. Ó sì wí pé, “Ẹ máa kíyèsára, kí a má báà mú yín sìnà: nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, tí yóò máa wí pé, ‘Èmi ní Kírísítì náà àkókò náà sì kù sí dẹ̀dẹ̀.’ Ẹ má ṣe tọ̀ wọ́n lẹ́yìn.

Lúùkù 21