16. Yóò wá, yóò sì pa àwọn alágbàtọ́jú náà run, yóò sì fi ọgbà àjàrà náà fún àwọn ẹlòmíràn.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, wọ́n ní, “Kí a má ri I!”
17. Nígbà tí ó sì wò wọ́n, ó ní, “Èwo ha ni èyí tí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé:“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀,Òun náà ni ó di pàtàkì igun kilé’?
18. Ẹnikẹ́ni tí ó ṣubú lu òkúta náà yóò fọ́; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí òun bá subú lù, yóò lọ̀ ọ́ lúúlúú.”