Lúùkù 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ Késárì Ògọ́sítù jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ìjọba Rosínú ìwé.

2. (Èyí ni ìkọ sínú ìwé ìkínní tí a ṣe nígbà tí Kíréníyù fi jẹ Baálẹ̀ Síríà.)

3. Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ rẹ̀ sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀.

4. Jóṣéfù pẹ̀lú sì gòkè láti Násárẹ́tì ìlú Gálílì, sí ìlú Dáfídì ní Jùdéà, tí à ń pè ní Bétílẹ́hẹ́mù; nítorí ti ìran àti ìdílé Dáfídì ní í ṣe,

Lúùkù 2