Lúùkù 18:35-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Bí ó ti súnmọ́ Jẹ́ríkò, afọ́jú kan jókòó lẹ́bá ọ̀nà ó ń ṣagbe:

36. Nígbà tí ó gbọ́ tí ọ̀pọ̀ ń kọjá lọ, ó bèèrè pé, kíni a lè mọ èyí sí.

37. Wọ́n sì wí fún un pé, “Jésù ti Násárẹ́tì ni ó ń kọjá lọ.”

38. Ó sì kígbe pé, “Jésù, ìwọ ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

39. Àwọn tí ń lọ níwájú bá a wí, pé, kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n òun sì kígbe sókè sí í pé, “Ìwọ Ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún mi!”

Lúùkù 18