Lúùkù 12:48-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

48. Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé bèèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé bèèrè sí i.

49. “Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kínni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí a ti dá a ná!

50. Ṣùgbọ́n èmi ní bamtísíìmù kan tí a ó fi bamitisí mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí!

51. Ẹ̀yin ṣe bí àlààáfíà ni èmi wá fi sáyé? Mo wí fún yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa.

Lúùkù 12