Lúùkù 12:12-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”

13. Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”

14. Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, tani ó fi mí jẹ onídájọ́ tàbí olùpí-ogúnn fún yín?”

15. Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì má a sọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”

16. Ó sì pa òwe kan fún wọn, pé, ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso:

Lúùkù 12