Lúùkù 11:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Jòhánù ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”

2. Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé:“ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run,kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.Kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe,bí i ti ọrun, Bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.

3. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.

4. Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá;nítorí àwa tìkarawa pẹ̀lú a máa dáríji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbésè,Má sì fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì.’ ”

Lúùkù 11