Lúùkù 1:60-65 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

60. Ìyá rẹ̀ sì dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ kọ́! Jòhánù ni a ó pè é.”

61. Wọ́n sì wí fún un pé, “Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ará rẹ̀ tí à ń pè ní orúkọ yìí.”

62. Wọ́n sì ṣe àpẹẹrẹ sí bàbá rẹ̀, bí ó ti ń fẹ́ kí a pè é.

63. Ó sì béèrè fún wàláà, ó sì kọ ọ wí pé, “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.” Ẹnu sì ya gbogbo wọn.

64. Ẹnu rẹ̀ sì ṣí lọ́gán, okùn ahọ́n rẹ̀ sì tú, ó sì sọ̀rọ̀, ó sì ń yin Ọlọ́run.

65. Ẹ̀rù sì ba gbogbo àwọn tí ń bẹ ní agbègbè wọn: a sì ròyìn gbogbo nǹkan wọ̀nyí ká gbogbo ilẹ̀ òkè Jùdéà.

Lúùkù 1