12. Nígbà tí Sakaráyà sì rí i, orí rẹ̀ wúlé, ẹ̀rù sì bà á.
13. Ṣùgbọ́n áńgẹ́lì náà wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, Sakaráyà: nítorí tí àdúrà rẹ gbà; Èlísábẹ́tì aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ ó sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Jòhánù.
14. Òun yóò sì jẹ́ ayọ̀ àti ìdùnnú fún ọ: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ.
15. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Olúwa, kì yóò sì mu ọtí-wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí-líle; yóò sì kún fún Èmí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.
16. Òun ó sì yí ènìyàn púpọ̀ padà nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí Olúwa Ọlọ́run wọn.