Léfítíkù 9:22-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Árónì sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí àwọn ènìyàn, ó sì súre fún wọn. Lẹ́yìn tó sì ti rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ sísun àti ẹbọ àlàáfíà, ó sọ̀kalẹ̀.

23. Mósè àti Árónì sì wọ inú àgọ́ ìpàdé. Nígbà tí wọ́n jáde, wọ́n súre fún àwọn ènìyàn, ògo Olúwa sì farahàn sí gbogbo ènìyàn,

24. Iná sì jáde láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì jó ẹbọ sísun àti ọ̀rá orí pẹpẹ. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì rí èyí wọ́n hó ìhó ayọ̀, wọ́n sì dojú bolẹ̀.

Léfítíkù 9