Léfítíkù 8:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé,

2. “Mú Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ mààlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀.

3. Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”

4. Mósè sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

Léfítíkù 8