20. Ṣùgbọ́n bí ẹni tí kò mọ́ bá jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tí ó jẹ́ tí Olúwa, a ó ge irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ̀.
21. Bí ẹnikẹ́ni bá fọwọ́ kan ohun aláìmọ́ yálà ohun àìmọ́ ti ènìyàn, ẹranko aláìmọ́, ohun àìmọ́ yówù kí ó jẹ́ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ìríra, tí ó sì tún jẹ́ ẹran ọrẹ àlàáfíà tó jẹ́ ti Olúwa, a ó gé irú ẹni bẹ́ẹ̀ kúrò lára àwọn ènìyàn rẹ.’ ”
22. Olúwa sọ fún Mósè pé,
23. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Ẹ má ṣe jẹ ọ̀rá mààlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́
24. Ẹ lè lo ọ̀rá ẹran tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko ìgbẹ́ pa, fún nǹkan mìíràn, ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́.