Léfítíkù 6:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Iná gbọdọ̀ máa jó lórí pẹpẹ títí, kò gbọdọ̀ kú.

14. “Ìwọ̀nyí ni ìlànà fún ẹbọ ohun jíjẹ, kí àwọn ọmọ Árónì gbé ẹbọ sísun náà wá ṣíwájú Olúwa níwájú pẹpẹ.

15. Kí àlùfáà bu ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára àti òróró pẹ̀lú gbogbo tùràrí tó wà lórí ẹbọ ohun jíjẹ náà kí ó sì sun ẹbọ ìrántí náà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa.

Léfítíkù 6