24. Ní ọdún ìdásílẹ̀ ilẹ̀ náà yóò padà di ti ẹni tí ó ni ín, lọ́wọ́ ẹni tí a ti rà á.
25. Gbogbo iye owó wọ̀nyí gbọdọ̀ wà ní ìbámu pẹ̀lú ṣékélì ibi mímọ́ (ogún gera).
26. “ ‘Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ ya gbogbo àkọ́bí ẹran sí mímọ́. Èyí jẹ́ ti Olúwa nípaṣẹ̀ òfin àkọ́bí: yálà kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni tàbí àgùntàn, ti Olúwa ni.
27. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹran tí kò mọ́, nígbà náà ni kí ó rà á padà gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀, kí ó sì fi ìdámárùn-ún lé e, tàbí bí a kò bá rà á padà kí ẹ tà á gẹ́gẹ́ bí ìdíyelé rẹ̀.
28. “ ‘Ohun tí a bá yà sí mímọ́ pátapáta láti ọwọ́ ẹnikẹ́ni sí Olúwa tàbí ẹranko tàbí ilẹ̀ tí ó jogún: òun kò gbọdọ̀ tàá kí ó rà á padà. Gbogbo ohun ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀ di mímọ́ jùlọ fún Olúwa.
29. “ ‘Ẹni tí ẹ bá ti yà sọ́tọ̀ fún pípa, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ràá padà, pípa ni kí ẹ paá.
30. “ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa.
31. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un.
32. Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.
33. Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”
34. Àwọn àṣẹ wọ̀nyí ni Olúwa pa fún Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orí òkè Sínáì.