12. Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
13. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì: kí ẹ̀yin má baà jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
14. “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí.
15. Bí ẹ̀yin bá kọ àṣẹ mi tí ẹ̀yin sì kórira òfin mi, tí ẹ̀yin sì kùnà láti pa ìlànà mi mọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin ti ṣẹ̀ sí májẹ̀mú mi.
16. Èmi yóò se àwọn nǹkan wọ̀nyí sí yín: Èmi yóò mú ìpáyà òjijì bá yín: àwọn àrùn afinisòfò, àti ibà afọ́nilójú, tí í pani díẹ̀díẹ̀. Ẹ̀yin yóò gbin èso ilẹ̀ yín lásán: nítorí pé àwọn ọ̀ta yín ni yóò jẹ gbogbo ohun tí ẹ̀yin ti gbìn.