Léfítíkù 25:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ẹ le bèèrè pé, “Kí ni àwa ó jẹ ní ọdún keje, bí a kò bá gbin èso tí a kò sì kórè?”

21. Èmi ó pèsè ìbùkún sórí yín tóbẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ yín yóò so èso tó tó fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn rẹ̀.

22. Bí ẹ bá gbin èso yín ní ọdún kejọ, àwọn èso ti tẹ́lẹ̀ ní ẹ ó máa jẹ, títí tí ìkórè ti ọdún kẹsàn-án yóò fi dé.

23. “ ‘Ẹ má ṣe ta ilẹ̀ yín ní àtàpa torí pé ẹ̀yin kọ́ lẹ ni-ín, ti Ọlọ́run ni, ẹ̀yin jẹ́ àlejò àti ayálégbé,

24. Ní gbogbo orílẹ̀ èdè ìní yín, ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.

25. “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá talákà, débi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.

Léfítíkù 25