Léfítíkù 24:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni bá ṣépè lé Ọlọ́run rẹ̀, yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa ni kí ẹ pa, kí gbogbo àpéjọpọ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa, yálà àlejò ni tàbí ọmọbíbí Ísírẹ́lì, bí ó bá ti sọ̀rọ̀òdì sí orúkọ Olúwa, pípa ni kí ẹ pa á.

17. “ ‘Ẹni tí ó bá gba ẹmi ènìyàn pípa ni kí ẹ pa á.

18. Ẹni tí ó bá gba ẹ̀mí ẹran ọ̀sìn ẹlòmíràn, kí ó dá a padà—ẹ̀mí dípò ẹ̀mí.

19. Bí ẹnìkan bá pa ẹnìkejì rẹ̀ lára: ohunkóhun tí ó ṣe ni kí ẹ ṣe sí i.

Léfítíkù 24