Léfítíkù 24:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara ólífì wá láti fi tan iná, kí àtùpà lè máa jò láì kú.

3. Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

4. Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá àtùpà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójojúmọ́.

5. “Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdáméjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n ẹfà (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan.

6. Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó gòólù bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa.

7. Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ ọrẹ iná sísun fún Olúwa.

Léfítíkù 24