Léfítíkù 24:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé

2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti mú òróró tí ó mọ́ tí a fún láti ara ólífì wá láti fi tan iná, kí àtùpà lè máa jò láì kú.

3. Lẹ́yìn aṣọ títa tibi àpótí ẹ̀rí tí ó wà ní inú àgọ́ ìpàdé, ni kí Árónì ti tan iná náà níwájú Olúwa, láti ìrọ̀lẹ́ di àárọ̀ lójojúmọ́. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀.

4. Àwọn Àtùpà tí wọ́n wà lórí ojúlówó ọ̀pá àtùpà tí a fi wúrà ṣe níwájú Olúwa ni kí ó máa jó lójojúmọ́.

Léfítíkù 24