Léfítíkù 23:25-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ ojúmọ́, ṣùgbọ́n ẹ mú ọrẹ tí a fi iná sun wá ṣíwájú Olúwa.’ ”

26. Olúwa sọ fún Mósè pé,

27. “Ọjọ́ kẹwàá oṣù keje yìí ni ọjọ́ ètùtù. Ẹ ni ìpàdé àjọ mímọ́, kí ẹ sì ṣẹ́ ara yín kí ẹ sì mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa.

28. Ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà, torí pé ọjọ́ ètùtù ni, nínú èyí tí a ń ṣe ètùtù fún yín níwájú Olúwa Ọlọ́run yín.

29. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣẹ́ ara rẹ̀ ní ọjọ́ náà ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

30. Èmi yóò pa ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́kiṣẹ́ ní ọjọ́ náà run kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

Léfítíkù 23