16. Nípa fífi ààyè fún wọn láti jẹ ọrẹ mímọ́ náà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi tí wọn yóò san nǹkan fún wá sórí wọn. Èmi ni Olúwa, tí ó sọ wọ́n di mímọ́.’ ”
17. Olúwa sọ fún Mósè pé,
18. “Sọ fún Árónì, àwọn ọmọ rẹ̀ àti fún gbogbo Ísírẹ́lì kí o sì wí fún wọn pé: ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín yálà ọmọ Ísirẹ́lì ni tàbí àlejò tí ń gbé ní Ísírẹ́lì bá mú ẹ̀bùn wá fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, yálà láti san ẹ̀jẹ́ tàbí ọrẹ àtinúwá.
19. Ẹ gbọdọ̀ mú akọ láìní àbùkù láti ara màlúù, àgùntàn tàbí ewúrẹ́, kí ó baà lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.
20. Ẹ má ṣe mú ohunkóhun tí ó ní àbùkù wá, torí pé kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín.