Léfítíkù 21:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.

19. Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,

20. tàbí tí ó jẹ́ abuké, tàbí tí ó ya aràrá tàbí tí ó ní àìsàn ojú tàbí tí ó ní egbò tàbí tí a ti yọ nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀.

21. Kò gbọdọ̀ sí iran àlùfáà tí ó jẹ́ alábùkù ara tí ó gbọdọ̀ wá fi iná sun ẹbọ sí Ọlọ́run. Nítorí pé ó jẹ́ alábùkù, kò gbọdọ̀ sún mọ́ tòsí láti gbé ẹbọ wá fún Olúwa.

Léfítíkù 21