13. “ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ Ọkùnrin rí.
14. Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀ sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbérè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
15. Kí ó má baà sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ”
16. Olúwa sì bá Mósè sọ̀rọ̀ pé,
17. “Sọ fún Árónì pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú ìran yín tí ó bá ní àrùn kan kò yẹ láti máa rú ẹbọ ohun jíjẹ́ fún mi.
18. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní àbùkù kò gbọdọ̀ sún mọ́ ibi ẹbọ náà. Kò gbọdọ̀ sí afọ́jú tàbí arọ, alábùkù ara tàbí àwọn tí ara wọn kò pé.
19. Kò gbọdọ̀ sí ẹnikẹ́ni yálà ó rọ lápá lẹ́sẹ̀,