Léfítíkù 20:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrin ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrin ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́.

26. Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀ èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.

27. “ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrin yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”

Léfítíkù 20