1. Olúwa sọ fún Mósè pé,
2. “Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.
3. “ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti bàbá rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.