Léfítíkù 14:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Kí ó fá gbogbo irun rẹ̀ ní ọjọ́ kéje: irun orí rẹ̀, irungbọ̀n rẹ̀, irun ìpéǹpéjú rẹ̀, àti gbogbo irun rẹ̀ tó kù. Kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì mọ́.

10. “Ní ọjọ́ kejọ kí ó mú àgbò méjì àti abo ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí wọn kò ní àlébù wá, pẹ̀lú ìdámẹ́wàá nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun tí à pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ àti òsùwọ̀n òróró kan.

11. Àlùfáà tí ó pè é ní mímọ́: yóò mú ẹni náà tí a ó sọ di mímọ́ àti ọrẹ rẹ̀ wá ṣíwájú Olúwa ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.

12. “Kí àlùfáà mú ọ̀kan nínú àwọn àgbò àti òróró kí ó sì fi rú ẹbọ ẹbí. Kí ó sì fí wọn níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífí.

13. Kí ó pa àgbò náà ní ibi mímọ́ nibi tí wọ́n ti ń pa ẹran ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ọrẹ ẹbọ sísun. Bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ẹbọ ẹ̀bi náà jẹ́ ti àlùfáà: ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.

14. Kí àlùfáà mú nínú ẹ̀jẹ̀ ẹbọ ẹ̀bi náà kí ó fi sí etí ọ̀tún ẹni náà tí a ó wẹ̀ mọ́, kí ó tún fi sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti orí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀.

15. Àlùfáà yóò sì mú díẹ̀ nínú òróró, yóò sì dà á sí àtẹ́lẹwọ́ òsì ara rẹ̀.

16. Yóò sì ti ìka ìfábẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ bọ inú òróró àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, yóò sì wọ́n díẹ̀ nínú rẹ̀ níwájú Olúwa nígbà méje.

Léfítíkù 14