Léfítíkù 14:52-57 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

52. Yóò fi ẹ̀jẹ̀ ẹyẹ náà, omi tí ó mọ́, ààyè ẹyẹ, igi sídà, hisopu àti òdòdó sọ ilé náà di mímọ́.

53. Kí àlùfáà ju ààyè ẹyẹ náà sílẹ̀ lẹ́yìn ìlú. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ilé náà. Ilé náà yóò sì mọ́.”

54. Àwọn wọ̀nyí ni ìlànà fún èyíkéyí àrùn àwọ̀ ara tí ó le è ràn ká (ẹ̀tẹ̀), fún làpálàpá,

55. fún ẹ̀tẹ̀ nínú aṣọ, tàbí ilé,

56. fún ìwú, fún èélá àti ibi ara dídán.

57. Láti mú kí a mọ̀ bóyá nǹkan mọ́ tàbí kò mọ́.Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún àrùn àwọ̀ ara tí ó ń ràn ká àti ẹ̀tẹ̀.

Léfítíkù 14