18. Àlùfáà yóò fi òróró tí ó kù ní àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ ra orí ẹni tí a ó wẹ̀ mọ́, yóò sì ṣe ètùtù fún un níwájú Olúwa.
19. “Àlùfáà yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀: yóò ṣe ètùtù fún ẹni tí a ó wẹ̀ kúrò nínú àìmọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà àlùfáà yóò pa ẹran ọrẹ ẹbọ sísun.
20. Yóò sì rú u lórí pẹpẹ pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ, yóò sì ṣe ètùtù fún un: Òun yóò sì di mímọ́.
21. “Bí ẹni náà bá jẹ́ tálákà tí kò sì le è kó gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, kí ó mú ọ̀dọ́ àgbò kan bí ẹbọ ẹbí, tí yóò fì, láti ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú ìdámẹ́wá òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára, a pò pọ̀ mọ́ òróró fún ọrẹ ohun jíjẹ òṣùwọ̀n òróró
22. àti àdàbà méjì tàbí ẹyẹlé méjì èyí tí agbára rẹ̀ ká ọ̀kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun.