Léfítíkù 12:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Obìnrin tí ó bá lóyún tí ó sì bí ọmọkùnrin, yóò wà láìmọ́ fún ọjọ́ méje bí ìgbà tí ó wà ní ipò àìmọ́ lákókò nǹkan oṣù rẹ̀.

3. Ní ọjọ́ kẹjọ ni kí ẹ kọ ọmọ náà ní ilà.

4. Obìnrin náà yóò sì dúró fún ọjọ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n (33) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan ohunkóhun tí ó jẹ́ mímọ́ tàbí kí ó lọ sí ibi mímọ́ Olúwa títí di ọjọ́ tí ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ yóò kọjá.

5. Bí ó bá ṣe obìnrin ni ó bí, fún ọ̀sẹ̀ méjì ni obìnrin náà yóò fi wà ní ipò àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Ó sì gbọdọ̀ dúró ní ọjọ́ mẹ́rìndínláàdọ́rin (66) láti di mímọ́ kúrò nínú ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

6. “ ‘Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ fún ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin bá kọjá kí ó mú ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá fún àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ẹbọ sísun àti ọmọ ẹyẹlé tàbí àdàbà kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

Léfítíkù 12