6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátakò ẹsẹ̀: àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.
7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹdẹ́ ya pátakò ẹṣẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.
8. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.
9. “ ‘Nínú gbogbo ohun tí Ọlọ́run dá tí ń gbé inú omi òkun, àti nínú odò: èyíkéyí tí ó bá ní lẹbẹ àti ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ́.
10. Ṣùgbọ́n nínú gbogbo ẹ̀dá tí ń gbé inú òkun àti nínú odò tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́, yálà nínú gbogbo àwọn tí ń rákò tàbí láàrin gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè yòókù tí ń gbé inú omi àwọn ni kí ẹ kórìíra.