23. Ṣùgbọ́n gbogbo kòkòrò oníyẹ́ yóòkù tí ó ní ẹsẹ̀ mẹ́rin ni kí ẹ kórìíra.
24. “ ‘Nípa àwọn wọ̀nyí ni ẹ le fi sọ ara yín di àìmọ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan òkú wọn yóò di aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
25. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé òkú wọn gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.
26. “ ‘Àwọn ẹranko tí pátakò wọn kò là tan tàbí tí wọn kò jẹ àpọ̀jẹ jẹ́ àìmọ́ fún yín. Ẹni tí ó bá fọwọ́ kan òkú èyíkéyí nínú wọn yóò jẹ́ aláìmọ́.