11. Nígbà tí ẹ ti kórìíra wọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran wọn: ẹ gbọdọ̀ kórìíra òkú wọn.
12. Ohunkóhun tí ń gbé inú omi tí kò ní lẹbẹ àti ìpẹ́ gbọdọ̀ já sí ìríra fún yín.
13. “ ‘Àwọn ẹyẹ wọ̀nyí ni ẹ gbọdọ̀ kórìíra tí ẹ kò sì gbọdọ̀ jẹ wọ́n torí pé ohun ìríra ni wọ́n: idì, oríṣìiríṣìi igun,
14. Àwòdì àti onírúurú àṣá,
15. Onírúurú ẹyẹ ìwò,