Léfítíkù 10:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá kúrò níbẹ̀, ẹ ó kùú, nítorí pé òróró ìtasórí Olúwa wà lórí yín” Wọ́n sì ṣe bí Mósè ti wí.

8. Olúwa sì sọ fún Árónì pé.

9. “Ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀ kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì tàbí ọtí líle mìíràn nígbàkigbà tí ẹ bá n lọ inú àgọ́ ìpàdé, bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ó kùú, èyí jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín láti ìrandíran.

10. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí.

Léfítíkù 10