4. kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹbọ sísun náà yóò sì jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò o rẹ̀, yóò sì jẹ́ ètùtù fún un.
5. Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájù Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í se ọmọ Árónì yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.
6. Òun yóò bó àwọ ara akọ ọ̀dọ́ màlúù náà, òun yóò sì gé e sí wẹ́wẹ́.
7. Àwọn ọmọ Árónì tí í ṣe àlùfáà yóò fi iná sí orí pẹpẹ, wọn yóò sì to igi sórí pẹpẹ náà.