Kólósè 4:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́;

3. Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣílẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kírísítì, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú:

4. Ẹ gbàdúrà pé kí èmí leè máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi.

5. Ẹ jẹ́ ọlọgbọ́n ni tí bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ńbẹ̀ lóde, kí ẹ sì máa ra ìgbà padà.

Kólósè 4