Kólósè 1:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.

12. Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yin láti jẹ́ alábàápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.

13. Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.

14. Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀.

Kólósè 1