22. Jóṣúà sì sọ fún àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ti wá ṣe ayọlẹ̀ náà wò pé, “Ẹ lọ sí ilé aṣẹ́wó nì, kí ẹ sì mu jáde àti gbogbo ohun tí í ṣe tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ tí búra fún un.”
23. Bẹ́ẹ̀ ní àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó lọ ṣe ayọ́lẹ̀wò wọlé lọ, wọ́n sì mú Ráhábù jáde, baba rẹ̀, ìyá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní. Wọ́n sì mú gbogbo ìdílé rẹ̀ jáde, wọ́n sì fi wọ́n sí ibìkan ní ìta ibùdó àwọn ará Ísírẹ́lì.
24. Nígbà náà ni wọ́n ṣun gbogbo ìlú náà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú u rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n fi fàdákà, wúrà ohun èlò-idẹ àti irin sínú ìsúra ilé Olúwa.