Jóṣúà 6:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wàyí oí a ti há Jẹ́ríkò mọ́lé nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ẹnikẹ́ni kò jáde, ẹnikẹ́ni kò sì wọlé.

2. Nígbà náà ni Olúwa wí fún Jóṣúà pé, “Wò ó, mo ti fi Jẹ́ríkò lé ọ lọ́wọ́ pẹ̀lú ọba rẹ̀ àti àwọn jagunjagun rẹ̀.

3. Ẹ wọ́de ogun yí ìlú náà ká lẹ́ẹ̀kan pẹ̀lú gbogbo àwọn jagunjagun. Ẹ ṣe èyí fún ọjọ́ mẹ́fà.

Jóṣúà 6