6. Àwọn ará Ísírẹ́lì rìn ní ihà fún ogójì (40) ọdún títí gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó tó ogun n jà nígbà tí wọ́n kúrò ni Éjíbítì fi kú, nítorí wọn kò gbọ́ràn sí Olúwa. Nítorí Olúwa ti búra fún wọn pé wọn kò ní rí ilẹ̀ tí òun ṣe ìlérí fún àwọn baba wọn láti fí fun wa, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.
7. Bẹ́ẹ̀ ni ó gbé àwọn ọmọ wọn dìde dípò wọn, àwọn wọ̀nyí sì ni Jóṣúà kọ ní ilà. Wọ́n wà ní aláìkọlà nítorí a kò tíì kọ wọ́n ní ilà ní ojú ọ̀nà.
8. Lẹ́yìn ìgbà tí gbogbo orílẹ̀ èdè náà kọ ilà tan, wọ́n dúró ní ibi tí wọ́n wà ní ibùdó títí ilà wọn fi jinná.
9. Nígbà náà ní Olúwa wí fún Jóṣúà pé, “Ní òní ni mo yí ẹ̀gàn Éjíbítì kúrò ní orí yín.” Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Gílígálì títí ó fi di òní yìí.
10. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹ́rìnlá (14) oṣù náà (oṣù kẹ́rin) (4) nígbà tí wọ́n pàgọ́ ní Gílígálì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ọdún Àjọ-ìrékọjá.