9. Jóṣúà sì to òkúta méjìlá (12) náà sí àárin odò Jọ́dánì fún ìrántí ní ọ̀kánkán ibi tí àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí ẹ̀rí dúró sí. Wọ́n sì wà níbẹ̀ di òní yìí.
10. Àwọn àlùfáà tí ó ru àpótí náà dúró ní àárin Jọ́dánì títí gbogbo nǹkan tí Olúwa pa láṣẹ Jóṣúà di síṣe ní paṣẹ̀ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún Jóṣúà. Àwọn ènìyàn náà sì yára kọjá,
11. bí gbogbo wọn sì ti rékọjá tán, ni àpótí ẹ̀rí Olúwa àti àwọn àlùfáà wá sí òdì kejì. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń wò wọ́n.
12. Àwọn ọkùnrin Rúbẹ́nì, Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè náà sì rékọjá ní ìhámọ́ra ogun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Móṣè ti pàṣẹ fún wọn.
13. Àwọn bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì (40,000) tó ti múra fún ogun rékọjá lọ ní iwájú Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò láti jagun.
14. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa gbé Jóṣúà ga ní ojú gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì bẹ̀rù u rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé e wọn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti bẹ̀rù Móṣè.
15. Olúwa sì sọ fún Jóṣúà pé,